Fídíò kan tí àwọn ènìyàn ti pín kiri tí se àfihàn Seyi Tinubu, ọmọ Bola Tinubu, Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, níbi tí àwọn ọmọ isẹ ologun ti tò lẹsẹẹsẹ láti bọ̀wọ̀ fún ọmọ Ààrẹ yìí, ti fa àríyànjiyàn lórí àwọn ohun ibaraẹnise ìgbàlódé.
Ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Kejìlá, ọdún 2024, Mahdi Shehu, ẹni tí ó máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, fi fídíò tí ó tó ìṣẹ́jú mẹ́rin síta, inú èyí tí ó ti sọ pé itolẹsẹẹsẹ àwọn ọmọ isẹ ológun láti bọ̀wọ̀ fún Seyi kò yẹẹ.
“Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nìkan ni àwọn ọmọ isẹ ológun ti máa ń tò yáányáán lẹsẹẹsẹ láti bọ̀wọ̀ fún ọmọ Tinubu nítorí pé Bola Tinubu jẹ́ Ààrẹ”, báyìí ni Shehu se fi ọ̀rọ̀ yìí síta lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise alámì krọọsí (X) tí a mọ sí Twitter tẹ́lẹ̀.
Àwọn ènìyàn ọgọrùn-ún àti mẹ́fà ẹgbẹ̀rún ló ti rí/wo fídíò yìí, àwọn ènìyàn ẹẹdegbẹrun ó dín ogún ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀ta ó dín ní marunlelogun ló pín ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ènìyàn ọtalenigba àti méjì ló sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn aadọjọ ló fi fídíò yìí pamọ.
Ní ọjọ́ ìsinmi, Atiku Abubakar, Ólùdíje fún Ipò Ààrẹ nígbà kan rí sọ pé itolẹsẹẹsẹ yìí kò bófin tàbí ètò ìjọba mú. Àwọn oluranlọwọ Atiku tí wọ́n máa ń rí sí ọ̀rọ̀ ìròyìn sọ pé àyẹ̀wò yẹ kó wà fún itolẹsẹẹsẹ yìí. Àwọn oluranlọwọ yìí sọ pé itolẹsẹẹsẹ yìí kó àbùkù bá bí àwọn ọmọ isẹ ológun se máa ń se nǹkan wọn.
KÍNI ITOLẸSẸẸSẸ YÁÁNYÁÁN TÍ ÀWỌN ỌMỌ ISẸ OLÓGUN MÁA Ń SE LÁTI BỌ̀WỌ̀ FÚN ÈNÌYÀN KAN?
Itolẹsẹẹsẹ tí àwọn ọmọ isẹ ológun máa ń se láti bọ̀wọ̀ fún tàbí yẹ ènìyàn sí jẹ́ ayẹyẹ tí àwọn sójà/ọmọ isẹ ológun (soldiers/military) máa ń se láti bọ̀wọ̀ fún àwọn ènìyàn pàtàkì tàbí láti bọ̀wọ̀ fún ènìyàn kan pàtàkì tó kú.
Itolẹsẹẹsẹ àwọn ọmọ isẹ ológun àti títòlẹsẹẹsẹ àwọn onisẹ ààbò tàbí àwọn ènìyàn jẹ́ ohun ibọwọfunni, biotilẹjẹpe wọn lè fara jọ bí àwọn ọmọ isẹ ológun se máa ń se.
Itolẹsẹẹsẹ àwọn ọmọ isẹ ológun, gẹ́gẹ́bí àjọ tí ó ń ṣètò ààbò fún ojú ọ̀nà tí àwọn awakọ̀ ń rìn (Federal Road Safety Commission-FRSC) se wí jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn sójà tí wọ́n máa ń yan, tí wọ́n sì máa ń se àfihàn àwọn ohun tí wọ́n ti kọ láti gbaradì fún wàhálà, ibaraẹniwi àti ìgbáradì.
Itolẹsẹẹsẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ bọ̀wọ̀ fún ènìyàn kan jẹ́ àwọn ènìyàn tí a yàn láti se ayẹyẹ ìbọ̀wọ̀fún láti kí àwọn ènìyàn pàtàkì kaabọ, dá ààbò bo àwọn ibi pàtàkì kan tàbí láti kópa nínú àwọn ayẹyẹ tí orílẹ̀ èdè tàbí àwọn ẹ̀ka orílẹ̀ èdè máa ń se.
Itolẹsẹẹsẹ láti bọ̀wọ̀ fún nnkan tàbí ènìyàn ní àwọn ènìyàn tí wọ́n kọ láti yan tàbí rìn bákan, èyí tí wọ́n máa ń se lọ́nà tí wọ́n máa ń se irú nnkan bẹ́ẹ̀ láti yẹ nnkan sí tàbí bọ̀wọ̀ fún nǹkan kan tí wọ́n máa ń se ní gbogbo ìgbà.
AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ THECABLE NEWSPAPER SE
Nígbà tí TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára se àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí, a ríi pé àwọn ènìyàn tí wọ́n gba Seyi ní àlejò nínú fídíò yìí ni wọ́n ń pè ní CADETN (Community Auxiliary Development for Effective Transformation Network), àwọn ọdọ kan tí wọ́n yọnda ara wọn fún ètò kan.
Láàárín àríyànjiyàn orí ayélujára, J.G. Fatoye, adarí àwọn ọdọ yìí, fi ọ̀rọ̀ kan síta ní ọjọ́ ajé, ó sọ pé Itolẹsẹẹsẹ ìbọ̀wọ̀fún ni, kìí se Itolẹsẹẹsẹ ìbọ̀wọ̀fún tàbí ayẹyẹ tí àwọn ọmọ isẹ ológun máa ń se.
“Gẹ́gẹ́bí àwọn ọdọ tó yọnda ara wọn fún ètò kan, a fẹ́ fi òye yé àwọn ènìyàn nípa Itolẹsẹẹsẹ ìbọ̀wọ̀fún. Ó wà nínú àkọsílẹ̀ pé wọ́n máa ń fi Itolẹsẹẹsẹ tí kì í se ti àwọn ọmọ isẹ ológun kí àwọn ènìyàn pàtàkì kaabọ síbi ayẹyẹ nítorí pé ayẹyẹ itunleaye àwọn ènìyàn se ni àti wí pé ẹgbẹ́ àwọn ọdọ ni,” báyìí ni ọ̀rọ̀ tí ẹgbẹ́ àwọn ọdọ yìí fi síta se wí.
Fatoye fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé Seyi nìkan kọ ní wọ́n máa ń se irú ìyẹnisi yìí fún.
“Àwọn tí wọ́n tò lẹsẹẹsẹ yìí ti yẹ àwọn ènìyàn pàtàkì bíi oluranlọwọ fún olórí kan fún àwọn ohun kan sí, wọn tún ti yẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn pàtàkì bíi minisita fún idagbasoke àwọn ọdọ sí, minisita fún tẹkinọlọji, oluranlọwọ pàtàkì fún Ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè àti ìdarí, adarí àwọn òṣìṣẹ́ ní Ìpínlẹ̀ Ogun àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn pàtàkì mìíràn tí wọ́n wá sí ibi ayẹyẹ náà sí,” báyìí ni Fatoye se wí.
“CADETN jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ọdọ, kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ isẹ ológun. Ẹgbẹ́ yìí kò sì ní ohunkóhun se pẹ̀lú àwọn ọmọ òṣìṣẹ́ ológun gẹ́gẹ́bí àwọn ènìyàn kan se sọ.”
“Ẹgbẹ́ yìí jẹ́ ẹgbẹ́ bíi Man O War, Peace Corps, Royal Ambassador, Man of Order, WAI Brigade àti àwọn mìíràn tí wọ́n máa ń yọnda ara wọn fún isẹ tó wù wọ́n (voluntary organisation), tí wọ́n máa ń wọ unifọọmu (uniform).”
Fatoye sọ pé kò sí ohunkóhun kan tí àwọn òṣìṣẹ́ ológun máa ń lò tí àwọn lò nígbà Itolẹsẹẹsẹ náà, ó ní àwọn ìbọn tí wọ́n fi máa ń ṣeré ni àwọn lò.
Ó ní kí àwọn ènìyàn yé máa sọ ọ̀rọ̀ tí kìí se òótọ́.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Kìí se Itolẹsẹẹsẹ tí àwọn ọmọ isẹ ológun máa ń se láti bọ̀wọ̀ fún tàbí yẹ ènìyàn tàbí nǹkan sí ni wọ́n se fún Seyi Tinubu.