Ọ̀rọ̀ kan lórí ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára tí sọ pé iye àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ (àwọn kristẹni) tí wọ́n ti pa ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ju àwọn ọmọ Palestine tí wọ́n pa ní Gaza láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2025 lọ.
Wọ́n fi ọ̀rọ̀ yìí síta ní ọjọ́ Satide, ọjọ́ kẹrindinlogun, oṣù kẹjọ, ọdún 2025, lórí ohun ìgbàlódé íbaraẹnise alámì krọọsi (X), tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀.
“Ní ọdún yìí, àwọn ẹlẹ́ṣin ìgbàgbọ́ tí wọ́n ti pa ní Nàìjíríà ju àwọn ọmọ Palestine tí wọ́n pa ní Gaza,” ẹnì kan tí ó ń jẹ́ Etal Yakoby lo fi ọ̀rọ̀ yìí síta fún àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ọgọsan ó lè ìkan àti ẹẹdẹgbẹta tí wọ́n ń tẹ̀lée lórí X.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rin àti méjìdínlọgbọn ló ti rí ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìlélọ́gbọ̀n ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹsan àti igba ló pín in, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀fà ló ti fi ọ̀rọ̀ yìí pamọ, àwọn ènìyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rin ló ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí.
Ṣé òótọ ni ọ̀rọ̀ yìí?
ỌMỌ PALESTINE MÉLÒÓ NI WỌ́N TI PA NÍ GAZA?
Láti bíi ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kẹjọ, ọdún 2025, iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ti pa ní Gaza Strip ti di ẹgbẹ̀rún mọkanlelogọta àti ẹẹdẹgbẹrun ó lé ní mẹrinlelogoji, gẹ́gẹ́bí WAFA, ilè isẹ ìròyìn kan se wí.
Iroyin yìí sọ pé àwọn ènìyàn tí wọ́n ju ìdajì, tí wọ́n jẹ́ àwọn ọmọdé àti obìnrin ni wọ́n ti fara kó wàhálà yìí tó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ keje, oṣù kẹwàá, ọdún 2023.
Ní ọjọ́ kẹrindinlogun, oṣù kẹjọ, ọdún 2025, ọjọ́ tí Yakoby sọ pé iye àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tí wọ́n ti pa ní Nàìjíríà ju gbogbo àwọn ọmọ Palestine tí wọ́n pa ní Gaza lọ, WAFA sọ pé iye àwọn ènìyàn tí wọ́n kú ní Gaza jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọkanlelọgọta àti ẹẹdẹgbẹrun din ni mẹta.
Ní ọdún 2025 nìkan, láti oṣù kìíní sí oṣù kẹjọ, àwọn ọmọ Palestine ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún àti igba ó lé ní mẹ́tàlélógún ni ìròyìn sọ pé wọ́n ti pa, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ tí World Health Organisation, àjọ àgbáyé fún ètò ìlera, fi síta (WHO’s Health Cluster unified dashboard). Idà àádọ́rin àwọn ènìyàn yìí ni wón jẹ́ obìnrin àti ọmọdé.
MÉLÒÓ NI ÀWỌN ẸLẸ́ṢIN ÌGBÀGBỌ́ TÍ WỌ́N TI PA NÍ NÀÌJÍRÍÀ NÍ 2025?
Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ kan tí International Society for Civil Liberties and Rule of Law (Intersociety), àwọn ẹgbẹ́ kan tí wọ́n máa ń gba ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣin ìgbàgbọ́ rò, fi síta se wí, bíi àwọn ẹlẹ́ṣin ìgbàgbọ́ tí wọ́n tó ẹgbẹ̀rún méje àti aadọrun-un ó dín ní mẹta ni wọ́n ti pa láàárín ọjọ́ kìíní, oṣù kìíní sí ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹjọ, ọdún 2025.
Intersociety sáábà máa ń fi ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n bá pa ní Nàìjíríà se ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń fi síta máa ń sọ pé àwọn fulani tí wọ́n máa ń da ẹran, àwọn ènìyàn tí wọ́n máa ń jà fún jihad àti àwọn oníwà líle ni wọ́n máa ń pa áwọn ènìyàn yìí.
ÀBÁJÁDE ÀYẸ̀WÒ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Àbájáde àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí tí CableCheck se fi yé wa pé iye àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tí Yakoby sọ pé wọ́n pa ní Nàìjíríà àti ìyè àwọn ẹlẹ́ṣin ìgbàgbọ́ tí Intersociety ní wọn pa ní Nàìjíríà yàtọ̀ sí ara wọn.
Láti ìgbà tí ogun ti bẹ̀rẹ̀ ní Gaza, àwọn ọmọ Palestine tí wọ́n lé ní ọgọ́ta ẹgbẹ̀rún ni wọ́n ti pa.
Ní ọdún sí ọdún, àwọn ọmọ Palestine tí wọ́n ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún ni wọ́n ti pa ní Gaza ni 2025, èyí tí ó ju iye àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní wọn pa ní Nàìjíríà lọ́nà méjì, tí ó ṣì tún lé, ní 2025.
BÍ CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Ọ̀rọ̀ tí Yakoby sọ pé iye àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tí wọ́n ti pa ní Nàìjíríà ju àwọn ọmọ Palestine tí wọ́n pa ní Gaza ní 2025 lọ yàtọ̀ sí àbájáde ayẹwo CableCheck. Biotilẹjẹpe Intersociety máa ń gbè sẹhin àwọn ẹlẹ́ṣin ìgbàgbọ́, iye àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tí Intersociety ní wọn pa kò tó iye àwọn ọmọ Palestine tí WHO ní wọn pa ní Gaza ní 2025.