Fọ́nrán fídíò akálékáko kan tó ń tàn ràn-ìn ní orí ayélujára ló gbé àhesọ kan pé àwọn ọlọ́ṣà kọlu ìjọ mímọ́ ti Kristi láti ọ̀run wá (Celestial church), tí ó wà ní ìlú Ọwọ, ní Ìpínlè Òndó.
“Ọkàn mí pòrurù, l’àná òde yí, àwọn apanilára kọlu ìjọ mímọ́ ti Kristi láti ọ̀run wá ní ìpínlè Òndó.” Ọ̀rọ̀ ìfòrí yì ni ẹnìkan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Florence ỌmọJésù, kọ sí abẹ́ fídíò náà, tí ó fi sí ojú òpó Tiktok rẹ̀, ọjọ́ kan lẹ́yìn tí àwọn apanilára kọlu ilé ìsìn St. Francis Catholic ni ilu ọwọ.
Fídíò náà káàkiri orí ayélujára lẹ́yìn ìkọlù tí ó gba ẹ̀mí lẹ́nu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó lọ sin Ọlọ́run ní ìlú Ọ̀wọ̀ ní ọjọ́ àìkú, ọjọ́ kàrún oṣù kẹfà, ọdún yìí.
“Àwọn Fúlàní tún kọlu ìjọ Celestial ní Àkúrẹ́,” ọ̀rọ̀ ìfòrí yí ni olùmúlò ìkànnì tiktok tí a mọ sì Ebenezer Àánú, kọ sí ojú òpó rẹ̀, tí wọ́n pín lórí ohun èlò fún íbáraẹnisọ̀rọ̀ (WhatsApp).
Fídíò náà, tíí ṣe ìṣẹ́jú-àáyá mẹ́tàlá s’àfihàn ilé kan tí wọ́n kùn ni funfun àti búlúù. Ó tún ṣ’àfihàn àwọn obìnrin àti ọmọdé tí wọ́n wọ aṣọ ádùrá funfun pẹ̀lú fìlà.
Nínú fónrán fídíò yí, a rí obìnrin kan tí ó gbé ọmọ kan dání, tí ó sì mú ikan lọ́wọ́, gbogbo wọ́n ń sáré láti má kó sí inú ewu.
Arábìnrin kàn fi’gbeta ní èdè Yorùbá. Ó wí pé “a ò lè lọ sí ilé, níbo l’ao sápamọ́ sí? Jésù!” ohùn yí l’agbọ́ nínú fídíò náà tó fihàn wí pé wàhálà wà.
Ní ojú òpó ìbánidọ́rẹ́ẹ́ Facebook, àwọn ènìyàn ti wo fídíò náà ní ìgbà egbàárin lé ní ọgọ́rùn-ún. Wọ́n sì fi fídíò náà sí ojú òpó abẹ́yẹfò Twitter.
Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí
Ní ọjọ́ ìsinmi, ojọ́ káàrùn, oṣù kẹfà, àwọn ọlọ́ṣà kọlu ilé ijọsin St. Francis Catholic ni ilu ọwọ ní Ìpínlẹ̀ Òndó.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá yí. Àwọn ẹlòmíràn sì f’arapa. Àwọn apanilára náà pa awọn ọmọdé ní ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wáyé ní ilé ìjọsìn Aguda lásìkò isin Ọjọ́ Pentikosti.
Ní Ọjọ́ Kẹtàdínlógún Oṣù Kẹfà, ìjọ náà ṣe ìsìnkú ọlọgọọrọ fún àwọn ènìyàn ogójì tó kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Isamudaju
TheCable kàn sí Fúnmilayo Ọdúnlami, agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlè Òndó, láti ṣe ìwádìí lóri ìkọlù ìjọ Celestial ní Ọ̀wọ̀.
Odunlami ní, “Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Òndó kò mọ̀ nípa ìkọlù kankan si ìjọ Celestial ní ìlú Ọwọ.”
Ìgbìmò aṣèwádìí wa ṣ’àyẹ̀wò ojú òpó ìjọ Celestial ti Ọ̀wọ̀ lórí ayélujára. A kàn sí adarí ibi-àbójútó Àlùfáà Kínní ati Ekeji, wọ́n fi yé wa pé fídíò náà wá láti ìjọ mímọ́ ti Kristi láti ọ̀run wá (Celestial Church), tí ó wà ní ìlú Ọwọ.
Ṣùgbọ́n, ẹnikẹ́ni kan kò kọlu ilé ìjọsìn náà ní ọjọ́ náà.
Joseph Olúwaségun, olùsọ ilé ìsìn kejì sọ wí pé: “íjáyà ni ó fá tí àwọn tí ó wá sin Ọlọ́run ní ọjọ́ náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣá sókè sódò lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìró ìbọn láti ilé ìsìn St. Francis Catholic.
Ṣáájú àsìkò yìí, Olúwaṣẹ́gun wí pé ìjọ náà n ṣe àjọyọ̀ ìkórè èwe.
Ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ọ̀daràn kò kọlù ilé ìsìn náà, àti wí pé gbogbo àwọn tí ó wà sin Ọlọ́run ló wà ní ayọ̀ àti àlàáfíà.
Àbájáde ìwádìí
Ìlú Ọwọ ni fónrán fídíò àwọn tí ó wá sin Ọlọ́run ní ìjọ mímọ́ Celestial ti wá, ṣùgbọ́n irọ́ gbáà ni àhesọ pé àwọn apanilára kọlu sọọsi (ìjọ) náà.