TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Ṣé Ruto ni olórí àkọ́kọ́ ní Áfíríkà ní ogún ọdún sí ìgbà yìí tí Amẹ́ríkà gbà ní àlejò?
Share
Latest News
BLIND SPOT: Nigeria’s shortcomings in the age of AI scams
The rise of deepfakes and the fight for digital truth
DISINFO ALERT: Health ministry debunks AI video claiming free nationwide diabetes treatment
Video wey show as ‘security operatives’ dey break into apartment no be from south-east
Íhé ńgósị́ ébé ńdị́ ǹché nà-ákpáká ụ́lọ̀ ésiteghị nà south-east
Ìṣẹ̀lẹ tí àwọn ‘òṣìṣẹ́ elétò ààbò’ fẹ́ fipá wọ ibùgbé kan kò ṣẹlẹ̀ ní gúúsù ilà oòrùn Nàìjíríà
Bidiyon da ake dangantawa da ‘jami’an tsaro’ da suka kutsa cikin gida ba daga kudu maso gabas ba ne
FACT CHECK: Video attributed to ‘security operatives’ breaking into apartment isn’t from south-east
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Ṣé Ruto ni olórí àkọ́kọ́ ní Áfíríkà ní ogún ọdún sí ìgbà yìí tí Amẹ́ríkà gbà ní àlejò?

Yemi Michael
By Yemi Michael Published March 18, 2024 6 Min Read
Share

William Ruto, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Kenya láìpẹ́ sọ pé òhun ni olórí Áfíríkà àkọ́kọ́ láti ogún ọdún sí ìgbà yìí tí Ààrẹ Amẹ́ríkà pé láti gbà ní àlejò.

Ó sọ ọ̀rọ̀ yìí níbi tí Benny Hinn ti ṣe ìyìn rere. Hinn jẹ́ pásítọ̀ tí àwọn ènìyàn mọ̀ púpọ̀ lórí ẹ̀rọ amóhunmáwòrán (television-tẹlifísọ̀n), tí ó ṣe ní Nairobi, olú ìlú orílẹ̀-èdè Kenya, ní ọjọ́ kẹrinlelogun àti karundinlọgbọn, oṣù kejì, ọdún 2024.

“Ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí pe Ààrẹ orílẹ̀-èdè Kenya kí ó wá bá ohùn ni àlejò. Ẹẹkan ni irú eléyìí tí ṣẹlẹ̀ ní ogún ọdún sí ẹ̀hìn” Ruto kéde ọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú ìdùnnú.

Àwọn ènìyàn ti wo ara ọ̀rọ̀ yi, èyí tí wọ́n gbé jáde lórí Citizen TV ní ọna ẹgbẹ̀rún igba àti ogójì ó dínkan láàárín ọjọ́ mọ́kànlá lórí ohun ìgbàlódé tí àwọn ènìyàn ti ń pín àwòrán nkan tàbí ti ara wọn (YouTube) ti o ni àwọn olùtẹ̀lé mílíọ̀nù márùn-ún ó dín ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà irínwó.

Ọ̀rọ̀ tí Ruto sọ yìí fàá kí àwọn ènìyàn Kenya fèsì lorisirisi ọ̀nà lórí ohun ìgbàlódé ìbáraẹnise tí a mọ̀ sí X (tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀). Àwọn kan pín ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn kan sì fi ìdùnnú hàn nípa ọ̀rọ̀ náà.

Lára àwọn tí ó ń lo X kan tí a mọ̀ sí Sirengo Maurice sọ pé Ruto fẹ́ fi lílọ rẹ̀ sí Amẹ́ríkà jẹ́ kí gbogbo àgbáyé fi mọ Kenya ni.

Ẹni mìíràn kan tí ó ń lo X sọ pé kílóde tí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa Amẹ́ríkà tí Ruto fẹ́ lọ níbi ìhìn rere.

KÍ NI ÌGBÀLÁLEJÒ ÀWỌN AṢOJÚ ÌJỌBA NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ MÌÍRÀN?

Ìgbàlálejò àwọn aṣojú ìjọba bíi Ààrẹ orílẹ̀-èdè tàbí àwọn aṣojú ìjọba míràn ní orílẹ̀ èdè mìíràn jẹ́ gbígba Ààrẹ tàbí àwọn aṣojú orílẹ̀-èdè kan láyè láti wá kí tàbí rí àwọn aṣojú orílẹ̀-èdè mìíràn níbi ibùjókòó ìjọba, ibi tí wọ́n ti máa gbà wọ́n ní àlejò.

Ààrẹ orílẹ̀-èdè tí ó fẹ́ gba àlejò ló máa ń fi ìwé pé aṣojú tàbí áwon aṣojú ìjọba tí wọ́nto  fẹ́ gbà ní àlejò.

Osita Agbu, pròfẹ́sọ̀             (ọ̀jọ̀gbọ́n/onímọ̀ ìjìnlẹ̀) nípa bí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń bá ara wọn ṣe ní Baze University, ní Nàìjíríà, sọ pé ìgbàlálejò àwọn aṣojú ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè kan ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe “pàtàkì gidi gan” nítorí pé ó máa ń fún àwọn aṣojú orílẹ̀-èdè ní àǹfààní láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn nkan tó ṣe kókó.

Amẹ́ríkà rí ìgbàlejò yìí bíi ọna fífi àjọṣepò, pàápàá jù lọ àjọṣepò tí ó dára hàn láàrin Amẹ́ríkà àti orílẹ̀-èdè tí wọ́n gbà ní àlejò. Ọjọ́ mẹ́rin ni wọ́n fi máa ń ṣe ìgbàlejò yìí. Wọ́n sì tún máa ń ṣe àwọn nǹkan míràn.

Jíjẹ àti mímu yóò wáyé nígbà ìgbàlejò yìí níbi tí a mọ̀ sí White House àti ifiwepe àwọn aṣojú orílẹ̀-èdè láti wá gbé fún ìgbà díẹ̀ níbi tí a mọ̀ sí Blair House, ibi tí wọ́n pèsè ṣílẹ̀ fún àwọn ènìyàn jankanjankan (pàtàkì) tí wọ́n fẹ́ wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn sí Washington D.C., ibùjókòó/ibi ìṣàkóso ìjọba Amẹ́ríkà.

A tún mọ Blair House gẹ́gẹ́bí ibi tí àwọn àlejò ìjọba máa ń dé sí.

A kìí sọ ọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó jọ mọ ọ̀rọ̀ isejọba nígbà yìí. Ayẹyẹ láti jẹ́ kí àjọṣepò gidi wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè méjì ni ó máa ń wáyé nígbà yìí.

ÀGBÉYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ RUTO

Láti lè mọ òótọ́ ọ̀rọ̀ Ruto, TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe àyẹ̀wò ìgbàlejò àwọn Ààrẹ Áfíríkà ní Amẹ́ríkà.

Ààrẹ Edwin Barclay ti orílẹ̀-èdè Làìbéríà (Liberia) ni Ààrẹ orílẹ̀-èdè Áfíríkà àkọ́kọ́ tí Amẹ́ríkà kọ́kọ́ gbà ní àlejò ní ọdún 1943 nígbà ìjọba Ààrẹ Franklin Roosevelt, ẹni tí ó jẹ́ Ààrẹ kejilelọgbọn ní Amẹ́ríkà.

Àmọ́, ní ọdún 2008-ọdún kẹrindinlogun sí ẹ̀hìn, George Bush, Ààrẹ kẹtalelogoji orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gba John Kuffour, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Ghana tẹ́lẹ̀ àti ìyàwó rẹ̀ ní àlejò.

Bush ní pé òhun mọ rírì wíwá  Kuffour àti àwọn tí wọ́n tẹ̀lée wá sí Amẹ́ríkà. Ó sì gbóríyìn fún Ààrẹ Ghana náà fún “àánú àti ìlàkàkà tàbí akitiyan rẹ̀ láti lè jẹ́ kí ìjọba tiwantiwa lọ sókè.”

Kí Kuffour tó lọ sí Amẹ́ríkà ní ọdún 2008, Bush, Ààrẹ Amẹ́ríkà ti gba Mwai Kibaki, Ààrẹ kẹta fún orílẹ̀-èdè Kenya ní àlejò ní oṣù kẹwàá, ọdún 2003.

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ

Irọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Ruto sọ yìí. Biotilẹjẹpe òhun ni Ààrẹ orílẹ̀-èdè Kenya àkọ́kọ́ tí Amẹ́ríkà gbà ní àlejò ní àárín ogún ọdún ó lé ní ìgbà díẹ̀ sí ẹ̀hìn, kìí ṣe Ààrẹ àkọ́kọ́ ní Áfíríkà tí Amẹ́ríkà gbà ní àlejò ni ogún ọdún sí ẹ̀hìn.

TAGGED: William Ruto

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Yemi Michael April 8, 2024 March 18, 2024
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print
Leave a comment Leave a comment

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

POPULAR POSTS

Advertisement

BLIND SPOT: Nigeria’s shortcomings in the age of AI scams

It sounded exactly like her, but it was not. Adeola Fayehun was thousands of miles…

August 12, 2025

The rise of deepfakes and the fight for digital truth

BY PRUDENCE OKEOGHENE EMUDIANUGHE On May 30, 2025, a 49-minute video surfaced on a YouTube…

August 12, 2025

DISINFO ALERT: Health ministry debunks AI video claiming free nationwide diabetes treatment

The ministry of health and social welfare has dismissed a viral claim alleging the launch…

August 12, 2025

Video wey show as ‘security operatives’ dey break into apartment no be from south-east

One Facebook user don claim sey video wey show as hooded armed security operatives dey…

August 7, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Video wey show as ‘security operatives’ dey break into apartment no be from south-east

One Facebook user don claim sey video wey show as hooded armed security operatives dey break into residential apartment hapun…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 7, 2025

Íhé ńgósị́ ébé ńdị́ ǹché nà-ákpáká ụ́lọ̀ ésiteghị nà south-east

Ótù onye na Facebook ekwuola na ihe ngosị ebe mmadụ na-agbaka ụlọ obibi mmadụ mere na south-east. N'ụbọchị iri abụọ…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 7, 2025

Ìṣẹ̀lẹ tí àwọn ‘òṣìṣẹ́ elétò ààbò’ fẹ́ fipá wọ ibùgbé kan kò ṣẹlẹ̀ ní gúúsù ilà oòrùn Nàìjíríà

Ẹni kan tí ó ń lo Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ lórí ayélujára sọ pé fídíò tí ó se afihan àwọn…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 7, 2025

Bidiyon da ake dangantawa da ‘jami’an tsaro’ da suka kutsa cikin gida ba daga kudu maso gabas ba ne

Wani ma’abocin amfani da shafin Facebook ya yi ikirarin cewa wani faifan bidiyo da ke nuna jami’an tsaro dauke da…

CHECK AM FOR WAZOBIA
August 7, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?