TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Ṣé òògùn ìbílẹ̀ lè ṣeé ìwòsàn ìju kí ó lọ pátápátá?
Share
Latest News
FACT CHECK: Is Nigeria 4th fastest-growing economy in the world in 2025?
FACT CHECK: How true are Obi’s claims about poverty rate in Nigeria, China and Indonesia?
FACT CHECK: No, Finnish court didn’t approve Simon Ekpa’s extradition to Nigeria
FACT CHECK: Is Cardinal Arinze eligible to be elected as the next Pope?
Rárá, Jonathan kò sọ pé Tinubu yóò se àṣeyọrí nínú ètò ìdìbò fún Ipò Ààrẹ ní ọdún 2027
A’a, Jonathan bai yi hasashen nasarar Tinubu a zaben shugaban kasa na 2027 ba
No, Jonathan no predict Tinubu victory for 2027 presidential election
Ḿbà, Jonathan ágbaghị àmà na Tinubu gà-èmérí ńtùlíáka ónyé ísíàlà ǹkè áfọ̀ 2027
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Ṣé òògùn ìbílẹ̀ lè ṣeé ìwòsàn ìju kí ó lọ pátápátá?

Oluyemi
By Oluyemi Published July 27, 2024 9 Min Read
Share
View of young woman suffering from stomachache on sofa at home. Woman sitting on bed and having stomach ache. Young woman suffering from abdominal pain while sitting on sofa at home

Atẹjade kan lórí ayélujára sọ pé òògùn ìbílẹ̀ nìkan ló lè ṣeé tọju oyún ìju tó sì máa jẹ́ kí aisedeedee ara yìí “kúrò lára” pátápátá.

Ẹnì kan fi ọ̀rọ̀ yìí síta ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù keje, ọdún 2024 láti sọ̀rọ̀ nípa fídíò tí Ini Dima-Okojie, gbajúmọ̀ obìnrin osere Nollywood kan sọ fún àwọn ènìyàn pé oyún ìju tí ó ń ṣe òhun tí òhun ṣe iṣẹ́ abẹ fún ní ọdún 2020 ti padà sí ní ṣe òhun.

Nínú fídíò yìí tí ènìyàn kan fi síta lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise tí a mọ̀ sí X (tí wọn ń pè ní Twitter tẹ́lẹ̀), Dima-Okojie sọ pé òhun fi ọ̀rọ̀ yìí síta láti lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ ìṣòro tí ó ń dojúkọ òhun àti láti gba àwọn ènìyàn tí wọ́n ní irú ìṣòro yìí níyànjú àti pé òhun mọ bí wàhálà aisedeedee ara yìí ṣe ń ṣe wọ́n.

Ó ní pé òhun kò ní kánjú ṣe iṣẹ́ abẹ mìíràn. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òhun yóò fara balẹ̀ wá ìtọ́jú tó péye láti lè dín ìju (fibroids) náà kù.

Ẹnì kan tí a mọ̀ sí @HerbalistChief lórí X dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ó ní òògùn ìbílẹ̀ nìkan ló lè wo oyún ìju. Ó ní iṣẹ́ abẹ kò lè ṣiṣẹ́.

“Kò sí iṣẹ́ abẹ tó lè ṣiṣẹ́ fún ìju. Ní pàtó, lẹ́hìn iṣẹ́ abẹ, ìju yìí yóò tún padà sí ara. Òògùn ìbílẹ̀ nìkan ló lè lé aisedeedee yìí lọ pátápátá,” báyìí arákùnrin yìí ṣe wí.

Àwọn ènìyàn ti rí ọ̀rọ̀ yìí ní ìgba mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹẹdẹgbẹrin, wọ́n fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ẹẹdẹgbẹrun, wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà pamọ́ ní ìgbà ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún kan àti ẹẹdẹgbẹrun ló pín ín, àwọn ènìyàn ọọdunrun ló sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

KÍNI ÌJU?

Ìju jẹ́ ohun tí ó máa ń yọ lára tí ó ní àrùn jẹjẹrẹ tí kò lè pani lára tí ó máa ń jẹ yọ nínú  ilé ọmọ àwọn obìnrin. A kò mọ àmọ̀daju tàbí ní àrídájú ìdí tí ìju fi máa ń jẹ yọ. Ìju máa ń gba ohun tí ó máa ń jẹ kí wọ́n yọ, tí ó sì máa jẹ́ kí wọ́n gbilẹ̀ láti ara ohun tí ó máa ń jẹ́ kí obinrin lè lóyún àti bímọ ni ìrọ̀rùn (estrogen).

Nípa ìdí èyí, ìju kìí sáábà máa ń ṣẹlẹ̀ kí àwọn obìnrin tó ba lágà tàbí ṣe ńnkan oṣù (menopause). Estrogen kìí fi bẹ́ẹ̀ wà lára àwọn obìnrin ní Ìgbà méjèèjì yìí.

Àmọ́sá, ìju máa ń farahàn lára àwọn bíi ìdajì àwọn ènìyàn tí ó máa ń ṣe.

Gẹ́gẹ́bí Alex Ades, onímọ̀ ìlera tó mọ̀ nípa òògùn tí àwọn ènìyàn lè lò fún àwọn àrùn tó ń ṣe àwọn obìnrin tó dàgbà àti àwọn tó kéré, pàápàá òògùn fún ọmọ bíbí àti oyún níní ṣe wí, ìkan nínú àwọn obìnrin márùn-ún máa rí dọkita elétò ìlera nígbà ayé wọn nítorí pé ìju ṣe  wọ́n.

Àwọn nǹkan tó maa ń jẹ́ kí a mọ bí wàhálà ìju ṣe máa pọ̀ lára ni bí ó ṣe tóbi tó àti ibi tí ó wà. Ìju lè fà kí ẹ̀jẹ̀ máa dà gidi lára obìnrin àti ìrora. Ìju kò kìí fa kí obìnrin má lè lóyún. Àmọ́, ó máa ń fa kí oyún wá lẹ̀ tàbí kí obìnrin pàdánù oyún.

AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ

Ìkan lára àwọn ọ̀rọ̀ orí X yìí ni pé iṣẹ́ abẹ kò lè ṣiṣẹ́ fún ìju.

Ọ̀rọ̀ yìí sọ pé “lẹ́hìn iṣẹ́ abẹ, ìju tún máa padà sára ẹni tó ń ṣe.”

Fẹhintọla Akintunde, onímọ̀ ìlera tó mọ̀ nípa òògùn tí àwọn ènìyàn lè lò fún àwọn àrùn tó ń ṣe àwọn obìnrin tó dàgbà àti àwọn tó kéré, pàápàá òògùn fún ọmọ bíbí ní ilé  ìwòsàn tí a mọ̀ sí Obafemi Awolowo University (OAU) Teaching Hospital sọ pé ìyàtọ̀ wà láàárín “ìtọ́jú” ati “ìwòsàn”.

Dọkita yìí ní pé ìju lè ṣeé tọju, kò lè ṣeé wòsàn. Ìdí ni pé àwọn ohun aisedeedee tí wọ́n máa ń yọ lára tí wọ́n ti yọ lára tẹ́lẹ̀ tí ìju fà nínú ilé ọmọ tún lè yọ padà, onímọ̀ ìlera yìí ló sọ bayii.

Ìtọ́jú tí àwọn elétò ìlera ń pè ní myomectomy yóò yọ ìju náà àti pé wàhálà tó ń fà fún ara yóò dá ọwọ dúró, báyìí ni Akintunde ṣe sọ fún TheCable, ìwé ìròyìn ayélujára.

“Bóyá ọ̀rọ̀ orí X yìí sọ pé ìju tún máa padà ṣe ẹni tí ó se. Níwọ̀n ìgbà tí obìnrin bá ní ìju, àwọn kòkòrò tí a kò lè fi ojú lásán rí tún máa padà yọ lára ẹni tí ó se ni bíi  ọdún márùn-ún, mẹ́fà, méje, mẹwa sí ìgbà tó ṣẹlẹ̀.

“Ó tún lè padà yọ. Àmọ́, ètò ìlera lè ṣeé ṣe fún ẹni tí ó se, aisedeedee tó fà fún ara yóò sì dínkù.

AYẸWO ÒÒGÙN ÌBÍLẸ̀ 

Funso Abdul, olùkọ́ ati profẹsọ (ọjọgbọn) onímọ̀ ìlera tó mọ̀ nípa òògùn tí àwọn ènìyàn lè lò fún àwọn àrùn tó ń ṣe àwọn obìnrin tó dàgbà àti àwọn tó kéré, pàápàá òògùn fún ọmọ bíbí àti oyún níní ti faculty of clinical sciences, University of Ilorin sọ pé àwọn onímọ̀ ìlera sìí ń wá òògùn tó lè wo ìju sàn.

“A kò tíì mọ̀ òògùn kankan bí mo ṣe ń ba yín sọ̀rọ̀ lọ́wọ́,” Abdul ló sọ báyìí. “Mo ti jẹ́ onímọ̀ nípa ìju láti 1994, n kò sì tíì rí òògùn ìbílẹ̀ tó lè wo ìju sàn. Àmọ́, mo ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrànlọ́wọ́ tí iṣẹ́ abẹ lè ṣe fún ẹni tí ìju ń ṣe,” olùkọ́ yìí ló sọ báyìí.

Akintunde tún jẹ́ olùkọ́ àgbà ní department of obstetrics and gynaecology, College of Health Sciences, OAU. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òògùn ìbílẹ̀ máa dá kún aisedeedee tí ìju máa ń fà.

“Ohun tí òògùn ìbílẹ̀ máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń jẹ́ kí àwọn aisedeedee yìí pọ̀ sí.

Àwọn aisedeedee irú èyí máa di omi, wọ́n sì máa padà lè, á tún sunki. Wọn sì lè fa ìrora. Wọ́n sì tún lè dí oyún níní lọ́wọ́. “Mo ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí kiní yìí ń ṣe tí wọ́n ní ìrora lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n lo òògùn ìbílẹ̀. Àwọn òògùn ìbílẹ̀ yìí máa ń fa wàhálà síi ni fún àwọn tí ìju ń ṣe. Òògùn ìbílẹ̀ kò leè ṣiṣẹ́ tí òògùn òyìnbó máa ṣe,” Akintunde ló sọ báyìí.

Abdul, ẹni tí ìwádìí rẹ̀ jẹ nípa bí àwọn ènìyàn ṣe ń bímọ, àwọn nǹkan tí ọmọ oyún lè mú lára ìyá rẹ àti ìju sọ pé òògùn, iṣẹ́ abẹ àti dídá bí ẹ̀jẹ̀ ṣe máa ń lọ sí ibi ilé ọmọ níbi tí ìju wà dúró jẹ́ àwọn ọ̀nà tí àwọn onímọ̀ ìlera máa ń lò láti tọju ìju.

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ 

Ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan sọ pé iṣẹ́ abẹ kò kìí ṣiṣẹ́ fún ìju kìí ṣe òótọ́. Àwọn ènìyàn lè tọju ìju pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ. Ìju lè padà sí ara ẹni tí ó ń ṣe. Àmọ́, eléyìí kò dá wa lójú.

Ní àfikún, a kò tíì rí àrídájú pé òògùn ìbílẹ̀ nìkan ló lè ṣiṣẹ́ fún ìju. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kò tíì fi ìdí èyí múlẹ̀ tàbí ríi pé òótọ́ ni.

TAGGED: Fact check in Yoruba, fake news, fibroid, Herbal remedies, News in Yorùbá

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Oluyemi July 27, 2024 July 27, 2024
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print
Leave a comment Leave a comment

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

POPULAR POSTS

Advertisement

FACT CHECK: Is Nigeria 4th fastest-growing economy in the world in 2025?

A viral post claims, based on International Monetary Fund (IMF) projections, that Nigeria ranks fourth…

May 9, 2025

FACT CHECK: How true are Obi’s claims about poverty rate in Nigeria, China and Indonesia?

Peter Obi, Labour Party (LP) presidential candidate in the 2023 elections, sparked a debate with…

May 5, 2025

FACT CHECK: No, Finnish court didn’t approve Simon Ekpa’s extradition to Nigeria

On Tuesday, some social media users and blog sites made a post claiming that a…

April 24, 2025

FACT CHECK: Is Cardinal Arinze eligible to be elected as the next Pope?

A social media user has claimed that Francis Arinze, a Roman Catholic cardinal, is the…

April 21, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Rárá, Jonathan kò sọ pé Tinubu yóò se àṣeyọrí nínú ètò ìdìbò fún Ipò Ààrẹ ní ọdún 2027

Ní ọjọ́ ajé, ọ̀rọ̀ kan to sọ pé Goodluck Jonathan, Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ sọ pé Ààrẹ Bọla Tinubu…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 20, 2025

A’a, Jonathan bai yi hasashen nasarar Tinubu a zaben shugaban kasa na 2027 ba

A ranar Talata ne wani rahoto da ke ikirarin cewa tsohon shugaban kasa Goodluck Jonathan ya yi hasashen nasarar Shugaba…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 20, 2025

No, Jonathan no predict Tinubu victory for 2027 presidential election

On Tuesday, one report wey claim sey former President Goodluck Jonathan predict President Bola Tinubu victory for di 2027 presidential…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 20, 2025

Ḿbà, Jonathan ágbaghị àmà na Tinubu gà-èmérí ńtùlíáka ónyé ísíàlà ǹkè áfọ̀ 2027

N’ubọchị Tuesde, ozi na-ekwu na onye bụburu onye isiala Naijiria, bụ Goodluck Jonathan, gbara àmà na onyeisiala Bola Tinubu ga-emeri…

CHECK AM FOR WAZOBIA
April 19, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?