TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Ǹjẹ́ wọ́n ti dá Ìpínlẹ̀ tuntun sílẹ̀ láti ara Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́?
Share
Latest News
Naijiria ọ̀ kàgbùrù ńkwékọ́rị́tá àzụ́máhị́á àkụ̀ ọ̀nàtàràchí yá nà US nwèrè n’íhì ḿmáchí visa?
Ǹjẹ́ Nàìjíríà dá àjọṣe lórí àwọn àlùmọ́ọ́nì láàárín òhun àti Amẹ́ríkà dúró nítorí visa?
Nigeria stop ‘mineral deal’ with US afta visa restriction?
Shin Najeriya ta dakatar da ‘yarjejeniyar ma’adinai’ da Amurka bayan hana biza?
FACT CHECK: Did Nigeria halt ‘mineral deal’ with US after visa restrictions?
FACT CHECK: Viral image depicting ‘Obasanjo prostrating for Ladoja’ photoshopped
Wike tụ̀rụ̀ àsị́. Peter Obi mèrè ńtụ̀líáká ọ̀chị́chị́ ḿpághárá m̀gbè ọ́ bụ̀ gọ́vánọ̀ Anambra
Irọ́ ni Wike pa. Peter Obi ṣètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Ǹjẹ́ wọ́n ti dá Ìpínlẹ̀ tuntun sílẹ̀ láti ara Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́?

Yemi Michael
By Yemi Michael Published November 2, 2024 4 Min Read
Share

 Ẹni kan tí ó ń lo Tiktok, ohun ìgbàlódé tí àwọn ènìyàn ti máa ń pín àwòrán tàbí fídíò ara wọn sọ pé àwọn asòfin tí fi ọwọ sì ìwé tí ó lè di òfin láti lè pín Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sí méjì.

Nínú fídíò bíi ìṣẹ́jú méjì, ẹni yìí tí a mọ̀ sí @Eddieblisshotline lórí Tiktok sọ pé wọ́n ti dá Ìpínlẹ̀ tuntun sílẹ̀/yọ Ìpínlẹ̀ tuntun láti ara Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹrindinlaadọta àti ẹẹdẹgbẹrun, wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ẹẹdẹgbẹrin ó lé ní marundinlogoji, wọ́n sì pín in ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ookandinlogoje.

Ẹni yìí sọ pé Ìbàdàn, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóò dá dúró bíi Ìpínlẹ̀ tí olú ìlú ẹ sì máa máa jẹ́ Ìbàdàn town.

Ẹni yìí tí a mọ̀ sí @Eddieblisshotline sọ pé kí àwọn ènìyàn mọ Ìpínlẹ̀ tí wọ́n yóò dára pọ̀ mọ́ lẹhin ìgbà tí wọ́n bá dá Ìpínlẹ̀ yìí silẹ.

“A mú ìròhìn tuntun wá fún yín, wọ́n ti pín Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sí méjì. Ẹ mọ̀ pé a ní Ìbàdàn àti Ọ̀yọ́, tí Ìbàdàn sì jẹ́ olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, nisinyii, wọ́n ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóò sì wà, tí Ọ̀yọ́ town yóò jẹ́ olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́,” arábìnrin yìí ló sọ báyìí.

“Bákan náà ni yóò se jẹ fún Ìbàdàn, èyí tí ó jẹ́ olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Nisinyii, Ìbàdàn yóò dá dúró bíi Ìpínlẹ̀, Ìbàdàn town yóò sì jẹ́ olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ìbàdàn. Eléyìí sì ti di òfin.”

Àwọn ènìyàn tí fi ọ̀rọ̀ yìí sórí fesibuuku/ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ (facebook) àti ohun ìgbàlódé ibaraẹnise tí àwọn ènìyàn ti ń pín àwòrán ara wọn (Instagram).

ǸJẸ́ WỌ́N TI DÁ ÌPÍNLẸ̀ MÌÍRÀN ṢÍLẸ̀ LÁTI ARA ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́?

Ní ọjọ́ kejilelogun, oṣù kẹwàá, ọdún 2024, àwọn ọmọ ilé igbimọ asofin kékeré (house of representatives) ka ìwé ohun tí ó lè di òfin yìí láti dá Ìpínlẹ̀ tuntun silẹ láti ara Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nígbà kejì.

Ẹni tí ó se agbekalẹ ìwé yìí ni Akeem Adeyemi, asofin (lawmaker/rep) tó ń ṣojú Ọ̀yọ́ federal constituency. Ó fẹ́ se àyípadà àwọn ibì kan nínú ìwé òfin fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ọdún 1999 (1999 constitution) láti lè dá Ìpínlẹ̀ tuntun náà sílẹ̀.

Ó sọ pé dídá Ìpínlẹ̀ náà sílẹ̀ se kókó nítorí pé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tóbi. Ó ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ló tóbi jù ní gúúsù ìwọ̀-oòrùn (southwest) Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹtalelọgbọn, ó si ní àwọn ènìyàn mílíọ̀nù márùn-ún àti ẹẹdẹgbẹta ó lé ní ọgọrin ẹgbẹ̀rún, ó lé ẹẹdẹgbẹrun ó dín ní mẹ́fà (àbájáde ikaniyan ọdún 2006).

Kí ìwé tí ó lè di òfin tó di òfin, àwọn asofin ilé igbimọ asofin kékeré àti ilé igbimọ asofin àgbà (senate) gbọ́dọ̀ jíròrò lórí rẹ̀ ní ìgbà mẹ́ta pẹlu àwọn ènìyàn tí ọ̀rọ̀ náà kàn ní àwùjọ. Lẹhin ìjíròrò yìí, wọ́n lè fọwọ́ sí tàbí kí wọ́n kọọ sílẹ̀.

Lẹhin ìgbà tí àwọn asofin bá fi ọwọ síi, wọ́n á fi ransẹ sí Ààrẹ kí òhun náà fọwọ́ síi.

BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ 

Ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé wọ́n ti dá Ìpínlẹ̀ tuntun sílẹ̀ láti ara Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kì í se òótọ́.

TAGGED: Fact check in Yoruba, new state creation, News in Yorùbá, Oyo state, State Creation

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Yemi Michael November 2, 2024 November 2, 2024
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print
Leave a comment Leave a comment

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

POPULAR POSTS

Advertisement

Naijiria ọ̀ kàgbùrù ńkwékọ́rị́tá àzụ́máhị́á àkụ̀ ọ̀nàtàràchí yá nà US nwèrè n’íhì ḿmáchí visa?

Ótù onye nà Facebook ekwuola na Naijiria emegwarụla mgbachibido visa nke mba US site n'ịkwụsị…

July 18, 2025

Ǹjẹ́ Nàìjíríà dá àjọṣe lórí àwọn àlùmọ́ọ́nì láàárín òhun àti Amẹ́ríkà dúró nítorí visa?

Ẹni kan tí ó ń lo Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ lórí ayélujára ti sọ pé…

July 18, 2025

Nigeria stop ‘mineral deal’ with US afta visa restriction?

One Facebook user claim sey Nigeria revenge against di recent United States visa restriction by…

July 18, 2025

Shin Najeriya ta dakatar da ‘yarjejeniyar ma’adinai’ da Amurka bayan hana biza?

Wani ma’abocin amfani da shafin Facebook ya yi ikirarin cewa Najeriya ta mayar da martani…

July 18, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Naijiria ọ̀ kàgbùrù ńkwékọ́rị́tá àzụ́máhị́á àkụ̀ ọ̀nàtàràchí yá nà US nwèrè n’íhì ḿmáchí visa?

Ótù onye nà Facebook ekwuola na Naijiria emegwarụla mgbachibido visa nke mba US site n'ịkwụsị nkwekọrịta azụmahịa akụ ọnatarachi dị…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 18, 2025

Ǹjẹ́ Nàìjíríà dá àjọṣe lórí àwọn àlùmọ́ọ́nì láàárín òhun àti Amẹ́ríkà dúró nítorí visa?

Ẹni kan tí ó ń lo Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ lórí ayélujára ti sọ pé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà hùwà sí…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 18, 2025

Nigeria stop ‘mineral deal’ with US afta visa restriction?

One Facebook user claim sey Nigeria revenge against di recent United States visa restriction by stopping one alleged mineral deal…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 18, 2025

Shin Najeriya ta dakatar da ‘yarjejeniyar ma’adinai’ da Amurka bayan hana biza?

Wani ma’abocin amfani da shafin Facebook ya yi ikirarin cewa Najeriya ta mayar da martani ne kan takunkumin da Amurka…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 18, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?