TheCable Fact Check
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Reading: Ǹjẹ́ Netflix yọ àwọn fíìmù Toyin Abraham nítorí pé ó lo agbára lọ́nà tí kò yẹ
Share
Latest News
Video wey show as ‘bridge collapse for Nasarawa’ na AI
AI ni wọ́n fi se fídíò afárá ti wọ́n ní ó wó ní Nasarawa
Íhé ńgósị́ ébé àkwà ḿmíri nà-ádà bụ̀ ǹkè é jìrì AI wòghárị́á
Bidiyon da ke nuna ‘gada ta rushe a Nasarawa’ AI ce ta samar
FACT CHECK: No, Nwifuru didn’t suspend officials for failing to attend child’s birthday party
FACT CHECK: Video showing ‘bridge collapsing in Nasarawa’ is AI-generated
MISINFO ALERT: Viral video of ‘foreign arms dealer’ in Zamfara is from 2021, says army
Ókwú Badenoch nà ụ́mụ̀ yá ápụ̀ghị̀ ínwétá íkíké ị́bụ ńdị́ Naijiria bụ̀ àsị́
Advertisement
Aa
TheCable Fact CheckTheCable Fact Check
Search
  • Home
  • Fact Check
  • Fake News
  • Check Am For Wazobia
Follow US

Ǹjẹ́ Netflix yọ àwọn fíìmù Toyin Abraham nítorí pé ó lo agbára lọ́nà tí kò yẹ

Oluyemi
By Oluyemi Published July 17, 2024 5 Min Read
Share

Àwọn atẹsita kan lórí àwọn ohun ibaraẹnise ìgbàlódé (social media) sọ pé Netflix (orí ohun tí wọn ti máa ń ṣe àfihàn fíìmù) ti yọ àwọn fíìmù tí Toyin Abraham, arábìnrin osere gbé jáde kúrò lórí ibi tí wọ́n ti ń gbé fíìmù jáde yìí.

Ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù keje, ọdún 2024, ẹni kan tí a mọ sí @Kadunaresident, ara àwọn tí wọn máa ń lo ohun ìgbàlódé alámì krọọsi (X) tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀ sọ pé ibi tí wọ́n ti máa ń ṣe àfihàn fíìmù náà ti yọ àwọn fíìmù tí osere náà wà nínú rẹ̀ kúrò lórí Netflix.

“Kére o: mo gbọ́ pé Netflix ti yọ gbogbo àwọn fíìmù Toyin Abraham lónìí? Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ jọ̀wọ́ ṣe pẹ̀lẹ́. Ìyá ènìyàn kan ni,” báyìí ni ẹni yìí tí ó ń lo X ṣe kọ atẹsita náà.

Àwọn ẹgbẹ̀ta ó lé ní mẹrindinlogoji ẹgbẹ̀rún ènìyàn ló rí ọ̀rọ̀ náà. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àti igba ló fẹ́ràn  ọ̀rọ̀ yì. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rin àti mẹ́jọ ló pín ín.

Àwọn ènìyàn pín ọ̀rọ̀ náà níbí àti níbí.

BÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢE RÍ

Abraham jẹ́ ìkan lára àwọn gbajumọ osere tí àwọn ènìyàn ti kàn ní àbùkù nítorí pé ó ti Ààrẹ Tinubu lẹ́hìn nígbà ìdìbò Ààrẹ ọdún 2023.

Àwọn ènìyàn fi ẹ̀sùn kan osere náà pé ó fi àwọn agbofinro mú ẹnì kan tí wọn ń pè ní Big Ayọ̀ tí ó máa ń ṣe iṣẹ́ kí àwọn ènìyàn lè mọ nǹkan síi ati ìyá rẹ̀ nítorí pé ó sọ ọ̀rọ̀ tí ó lè ba Abraham lórúkọ jẹ́.

Ayọ̀ fi ẹ̀sùn kan Abraham pé ó gba owó lọ́wọ́ Tinubu láti fi tọju orí ọkọ rẹ̀ tí a mọ̀ sí Kolawole Ajeyemi tí irun rẹ̀ ti pá jẹ se.

“Arábìnrin @toyin_abraham1, walai aiye ẹ ti tà! O gba owó Tinubu, o fi ṣe hair transplant fún ọkọ ẹ. Òpònú aláìnílàákàyè,” báyìí ni atẹsita yìí ṣe wí. Wọn ti yọ ọ̀rọ̀ náà kúrò lórí X.

Nígbà tí osere náà ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ohun ìgbàlódé tí àwọn ènìyàn ti máa ń pín àwòrán nǹkan tàbí ti ara wọn (Instagram), ó sọ pé ọ̀rọ̀ yìí kìí ṣe òótọ́. Ó ní òhun kò sọ pé kí àwọn agbofinro mú ìyá Ayọ̀. Ó sọ pé nǹkan tí òhun ṣe ni pé òhun fi ẹjọ́ náà sún àwọn ẹ̀ka ìjọba tó ń rí sí ìwà tí kò dára lórí ayélujára.

Ó ní òhun kò ní gbà kí àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ tí kò dára sí àwọn ọmọ òhun. Ó ṣe ìlérí pé òhun yóò dojú ìjà kọ àwọn tí wọn máa ń sọ̀rọ̀ òhun ní àìda ní orí ayélujára àti pé òhun yóò sì bá wọn fàá gan-an ni.

Ọ̀rọ̀ yìí bí àwọn ènìyàn nínú lórí X. Lára àwọn ènìyàn yìí sì kọ ìwé sì Netflix àti Prime Video (ibì kan mìíràn tí wọn ti máa ń ṣe àfihàn fíìmù lórí ayélujára) pé kí wọ́n yọ àwọn fíìmù rẹ̀ kúrò lórí àwọn ibi tí wọ́n ti ń fi fíìmù hàn yìí nítorí pé osere náà ‘lo agbára ní ọ̀nà tí kò yẹ.”

Ikan lára àwọn tí ó ń lo X fi lẹ́tà (ìwé) yìí hàn, ó sì ní kí àwọn ènìyàn má wo fíìmù osere náà. Àwọn ènìyàn mìíràn dá ẹ̀rù ba osere náà. Wọ́n ní pé àwọn yóò fi ẹjọ́ rẹ̀ sun àwọn tí wọn ni àwọn ohun ìgbàlódé ibaraẹnise (social media owners) tí  àwọn agbofinro kò bá tú big Ayọ̀ sílẹ̀ ní àtìmọ́lé.

ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ

Láti lè mọ bóyá irọ tàbí òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí, TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe àyẹ̀wò bóyá Netflix ti yọ àwọn fíìmù osere yìí.

A ríi pé àwọn fíìmù tí osere náà wà nínú rẹ̀ bíi ‘Ijakumọ’, ‘malaika’, ‘prophetess’, ‘Elevator Baby’, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn sì wà lórí Netflix.

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ

Netflix kò yọ àwọn fíìmù Abraham tàbí dá síse àfihàn àwọn fíìmù rẹ̀ dúró.

TAGGED: Fact check in Yoruba, Netflix, News in Yorùbá, Toyin Abraham

Please send your feedback, claims to fact check and corrections requests to [email protected]

Oluyemi July 17, 2024 July 17, 2024
Share this Article
Facebook Twitter Email Copy Link Print
Leave a comment Leave a comment

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

POPULAR POSTS

Advertisement

Video wey show as ‘bridge collapse for Nasarawa’ na AI

One video wey show as bridge dey collapse dey waka for social media, especially Facebook.…

July 29, 2025

AI ni wọ́n fi se fídíò afárá ti wọ́n ní ó wó ní Nasarawa

Àwọn ènìyàn ti ń pín fídíò kan tí ó ṣe àfihàn afárá tí ó wó…

July 29, 2025

Íhé ńgósị́ ébé àkwà ḿmíri nà-ádà bụ̀ ǹkè é jìrì AI wòghárị́á

Ótù ihe ngosị na-agbasa na sosha midia, ma na-egosị ebe àkwà mmịrị na-ada. A kọwara…

July 29, 2025

Bidiyon da ke nuna ‘gada ta rushe a Nasarawa’ AI ce ta samar

Bidiyon da ke nuna yadda wata gada ta ruguje ta ke yawo a shafukan sada…

July 29, 2025
Advertisement
Advertisement

YOU MAY ALSO LIKE

Video wey show as ‘bridge collapse for Nasarawa’ na AI

One video wey show as bridge dey collapse dey waka for social media, especially Facebook. For di five-second video, di…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 29, 2025

AI ni wọ́n fi se fídíò afárá ti wọ́n ní ó wó ní Nasarawa

Àwọn ènìyàn ti ń pín fídíò kan tí ó ṣe àfihàn afárá tí ó wó lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 29, 2025

Íhé ńgósị́ ébé àkwà ḿmíri nà-ádà bụ̀ ǹkè é jìrì AI wòghárị́á

Ótù ihe ngosị na-agbasa na sosha midia, ma na-egosị ebe àkwà mmịrị na-ada. A kọwara na ọ bụ na India…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 29, 2025

Bidiyon da ke nuna ‘gada ta rushe a Nasarawa’ AI ce ta samar

Bidiyon da ke nuna yadda wata gada ta ruguje ta ke yawo a shafukan sada zumunta musamman a Facebook a…

CHECK AM FOR WAZOBIA
July 29, 2025

CableCheck seeks to provide reliable tools and resources for readers to tackle the menace of fake and misleading materials constantly pushed into the public space from various sources. We monitor the accuracy of claims made in traditional and social media. We also provide a tracker to hold politicians and policymakers accountable for the plans and promises they make to the public. CableCheck is a project of the Cable Newspaper Journalism Foundation (CNJF), supported by the MacArthur Foundation and implemented by TheCable newspaper.

Follow US: 

LINKS

  • Contact
  • About Us
  • Non-Partisanship Policy
  • Funding
  • Correction Policy
© Copyright TheCable. All Rights reserved.
Welcome Back!

Sign in to your account

Lost your password?