Adesanmi Akinsulore, profẹsọ (ọjọgbọn) ní Obafemi Awolowo University (OAU) àti Obafemi Awolowo University Teaching Hospital (OAUTH) (ilé ìwòsàn tí a ti ń kọ nípa ètò ìlera), ní Ilé ifẹ, ní Ìpínlẹ̀ Ọsun, sọ pé Nàìjíríà ni Orílẹ̀ èdè kẹfà tí àwọn ènìyàn ti ń gba ẹ̀mí ara wọn jù ní àgbáyé.
Gẹ́gẹ́bí ìwé ìròyìn Punch se wí, Akinsulore sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ibi idanilẹkọ, ètò kan tí Still Waters Mental Health Foundation se agbekalẹ rẹ̀ ní Ladoke Akintola University of Technology (LAUTECH), Ogbomoso, Oyo State.
Ó ní ìjọba gbọ́dọ̀ gbé igbesẹ gidi laifi àsìkò ṣòfò nípa ọ̀rọ̀ yìí, pàápàá jù lọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́.
“Ẹni kan gba ẹ̀mí ara rẹ̀ láàrin àwọn marunlelogun tí wọ́n gbé irú igbesẹ yìí. Ní ọdún 2021, gbígba ẹ̀mí ara ẹni jẹ́ nnkan kẹta tí ó fa ikú fún àwọn ọdọ tí ọjọ́ orí wọn kò ju ọdún mẹẹdogun sí ọdún mọkandinlọgbọn lọ ní àgbáyé”, báyìí ni wọ́n ní Akinsulore se wí.
“Ojúṣe gbogbo wa ni làti dojú kọ ìṣòro yìí. A gbọ́dọ̀ fọwọ́ so ọwọ pọ̀ láti se atilẹyin fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti kó ògo ayé já.”
ALAYE NÍPA KÍ ÈNÌYÀN GBA Ẹ̀MÍ ARA RẸ̀
Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ tí World Health Organization (WHO), àjọ eleto ìlera fún àgbáyé se sọ, iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ju ẹẹdẹgbẹta ẹgbẹ̀rún ni wọ́n gba ẹ̀mí ara wọn ní ọdọọdún. WHO sọ pé ikọọkan nínú àwọn ènìyàn yìí ló fẹ́ gba ẹ̀mí ara rẹ̀ bíi ìgbà ogún.
Àjọ yìí sọ pé gbígba ẹ̀mí ara ẹni jẹ ohun kẹrin tí ó máa ń fa ikú fún àwọn ènìyàn jù láàárín àwọn ènìyàn tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹẹdogun sí ọdún mọkandinlọgbọn (ọkùnrin àti obìnrin) ní gbogbo àgbáyé. WHO fi kún ọ̀rọ̀ wọn pé ìdá àádọ́rin pẹ̀lú mẹ́ta gbígba ẹ̀mí ara ẹni yìí máa ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn orílẹ̀ èdè tí àwọn ènìyàn kò ti lowo lọ́wọ́.
Àwọn ohun tí ó lè fa kí ènìyàn gba ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ìrẹ̀wẹ̀sì, aisedeedee tí ọtí máa ń fà, àdánù/kí ènìyàn pàdánù nǹkan, aisowo/ìṣòro tó jọ mọ owó, airẹnibase/didawa, kí a máa jẹ́ kí ènìyàn rò pé kò daaato, wàhálà ibaraẹnise, ara riro àti àìsàn, rògbòdìyàn, èébú àti ìṣẹ̀lẹ̀ airotẹlẹ.
Àwọn ènìyàn tí ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ènìyàn kan tí wọ́n gba ẹ̀mí ara wọn tàbí tí wọ́n fẹ́ gba ẹ̀mí ara wọn laipẹ.
Ní oṣù kẹwàá, ọdún 2024, Ìròyìn sọ pé Ọmọlará Bámidélé, arákùnrin kan tí ó jẹ́ ẹni ọdún mejidinlọgọta pa ara rẹ̀ ní ìlú Igburowo, ní ìjọba ìbílẹ̀ Odigbo, ní Ìpínlẹ̀ Ondo.
Àwọn ara ìlú yìí sọ pé wọ́n rí òkú Bámidélé ní ọ̀nà kan pẹ̀lú ohun kan tí wọ́n ń pè ní “Sniper”, ohun kan tí wọ́n fi kẹ́míkà se.
Ní oṣù kẹsàn-án, ọdún 2024, Gabriel Magaji, ọmọ ọdún mejidinlogoji, tí ó ń gbé ní Masaka, ní ìjọba ìbílẹ̀ Karu, ní Ìpínlẹ̀ Nasarawa, pa ara rẹ̀, nítorí pé ìyàwó rẹ̀ ń yan àlè.
ǸJẸ́ LÓÒÓTỌ́ NI PÉ NÀÌJÍRÍÀ NI ORÍLẸ̀ ÈDÈ KẸFÀ TÍ ÀWỌN ÈNÌYÀN TI Ń GBA Ẹ̀MÍ ARA WỌN JÙ NÍ ÀGBÁYÉ?
TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára gbìyànjú láti fi ọ̀rọ̀ wá Akinsulore lẹ́nu wò, ṣùgbọ́n kò fẹ́ jẹ́ kí a mọ ibi tí ó ti rí ọ̀rọ̀ yìí.
Àmọ́sá, àyẹ̀wò tí TheCable se fi ye wa pé, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ tí WHO se wí lórí bí àwọn ènìyàn se gba ẹ̀mí ara wọn, èyí tí àjọ yìí sọ pé àwọn se atunse sí ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù Kínní, ọdún 2024, Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀ èdè kẹtadinlọgọjọ ní gbogbo àgbáyé tí àwọn ènìyàn bíi mẹ́rin ti máa ń gba ẹ̀mí ara wọn nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún.
Àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́wàá tí àwọn ènìyàn ti máa ń gba ẹ̀mí ara wọn jù ní àgbáyé àti bí àwọn orílẹ̀ èdè yìí se tẹle ara wọn ni Lesotho (ìdá mejilelaaadọrin níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn), Guyana (ìdá ogójì níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn), Eswatini (ìdá bíi ọgbọ́n níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn), Republic of Korea (ìdá bíi mọkandinlọgbọn níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn), Kiribati (ìdá bíi mọkandinlọgbọn níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn) àti Micronesia (ìdá mejidinlọgbọn ó lé ní díẹ̀ níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn).
Àwọn orílẹ̀ èdè yòókù ni Lithuania (ìdá mẹrindinlọgbọn ó lé díẹ̀ níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn), Suriname (ìdá marundinlọgbọn ó lé díẹ̀ níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn), Russian Federation (ìdá marundinlọgbọn ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún) àti South Africa (ìdá bíi mẹrinlelogun ló máa ń gba ẹ̀mí ara wọn níbẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún).
Ayẹwo wa fihàn pé Micronesia ni Orílẹ̀ èdè kẹfà tí àwọn ènìyàn ti ń gba ẹ̀mí ara wọn jù ní àgbáyé.
BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ
Nàìjíríà kọ ni Orílẹ̀ èdè kẹfà tí àwọn ènìyàn ti ń gba ẹ̀mí ara wọn jù ní àgbáyé. Èyí túmọ̀ sí pé ọ̀rọ̀ tí Akinsulore sọ nípa gbígba ẹ̀mí ara ẹni ní Nàìjíríà kìí se òótọ́.