Ọ̀rọ̀ kan sọ pé Donald Trump, ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti dúnkokò pé òhun yóò mú Bọ́lá Tinubu, ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láàárín wákàtí mẹrinlelogun tí àwọn tí wọ́n ń sọ́ọ kò sì ní mọ̀.
“Tí Amẹ́ríkà bá fẹ́ mú ààrẹ Nàìjíríà, a lè seé láàárín ọjọ́ kan tí àwọn tí wọ́n ń sọ́ọ kò ní mọ̀ títí tí a fi máa setán,” báyìí ni ọ̀rọ̀ yìí tí ẹnì kan fi síta ní ọjọ́bọ̀ sọ pé Trump se sọ.
“Ní ọdún márùn-ún ṣẹ́hìn, àwọn òṣìṣẹ́ ológun wọ Nàìjíríà láti gba àwọn ọmọ Amẹ́ríkà tí wọ́n wà ní àhámọ́ ṣílẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ ológun Nàìjíríà kò sì mọ̀ pé a wá gba àwọn ènìyàn yìí sílẹ̀. Eléyìí fi yé wa pé àwọn òṣìṣẹ́ ológun Nàìjíríà kò lágbára, wọn kò sì kóra jọ bó se yẹ,” ara ọ̀rọ̀ tí ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi síta yìí sọ pé Trump sọ nìyí.
“Nàìjíríà gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Amẹ́ríkà kò kí ń sọ̀rọ̀ jù. A máa ń se nnkan wa ní kíákíá, a sì ma sé dáadáa,” ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi síta yìí ló tún sọ báyìí.


Wọ́n fi ọ̀rọ̀ yìí síta lórí Facebook, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ orí ayélujára àti TikTok, ohun ìgbàlódé orí ayélujára tí àwọn ènìyàn ti máa ń fi àwòrán tàbí fídíò síta.
Sé Trump dúnkokò/halẹ̀ pé òhun yóò mú Tinubu?
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Àyẹ̀wò ìkan nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó se kókó nínú ọ̀rọ̀ yìí tí Cablecheck, ti TheCable Newspaper, ìwé and ìròyìn orí ayélujára se fihàn pé àwọn ènìyàn fi ọ̀rọ̀ yìí síta lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára (social media accounts) àti àwọn ibi tí wọ́n ti máa ń fi ìròyìn síta (news platforms) láàárín wákàtí mẹrinlelogun.
CableCheck ṣàkíyèsí pé ọ̀rọ̀ yìí tí ẹnì kan kọ́kọ́ fi síta jáde lórí YouTube, ohun ìgbàlódé orí ayélujára tí àwọn ènìyàn ti máa ń fi àwòrán tàbí fídíò síta ní ọjọ́ keje, osù kọkànlá, ọdún 2025 ni ibi kan tí wọ́n ń pè ní NedMedia. NedMedia ní àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún igba àti mẹ́tàlá tí wọ́n fẹ́ràn láti máa wo àwọn nǹkan tí wọ́n bá fi síta.
“Trump ń gbèrò láti yọ Tinubu kó tó dá sí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà? Mike Arnold sọ pé orílẹ̀ èdè US lè se nnkan yìí tí Tinubu bá kùnà láti se ohun tó yẹ kó ṣe,” báyìí ni àkòrí fídíò yìí se sọ.
Àwọn ènìyàn ti wo fídíò ọ̀rọ̀ yìí ní ìgbà ẹgbẹ̀rún àádọ́rin àti ọọdunrun ó dín ní marundinlaaadọta.
Fídíò yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àyọkà/àyọsọ kan láti inú fídíò kan tí Trump se, níbi tí ó ti ń se ìkìlọ̀ pé US “máa se áwọn nǹkan tí kò nìí dùn mọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà nínú.”
Trump sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ kẹfà, osù kọkànlá, ọdún 2025 nígbà tí ó se ìkìlọ̀ pé àwọn òṣìṣẹ́ ológun US lè wá sí Nàìjíríà “tìbọntìbọn láti pa áwọn ọmọ ẹlẹ́ṣin ìmàle tí wọ́n máa ń hùwà tó ń já àwọn ènìyàn láyà (Islamic terrorists) tí wọ́n ń hu ìwà burúkú yìí.”
Ààrẹ Amẹ́ríkà ń sọ̀rọ̀ lórí ohun tó pé ní ìpakúpa tí wọ́n ń pa àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ ní Nàìjíríà.
Trump kò sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ ológun yóò mú Tinubu láàárín wákàtí mẹrinlelogun.
Nínú fídíò yìí lórí YouTube, ẹni tó ń sọ̀rọ̀ nínú fídíò yìí sàfihàn ọ̀rọ̀ kan tí Mike Arnold, ara àwọn olórí ibì kan tí wọ́n ń pè ní Texas ni US fi síta lórí X, ohun ìgbàlódé íbaraẹnise alámì krọọsi ti wọ́n ń pè ní Twitter tẹ́lẹ̀ tó sọ pé Amẹ́ríkà ń gbèrò láti “yọ” Tinubu kúrò nípò ààrẹ.
Arnold sọ pé ọ̀rọ̀ orí X yìí kò sọ irú nǹkan báyìí. CableCheck ṣàkíyèsí pé ẹni tó sọ̀rọ̀ nínú fídíò yìí gangan ló sọ ọ̀rọ̀ yìí.
“Tinubu gan rò pé isẹ́/ojúṣe òhun ni láti yan adari fún àwọn òṣìṣẹ́ ológun tó máa se isẹ́ náà,” báyìí ni ọkùnrin tó ń sọ̀rọ̀ nínú fídíò yìí se wí nípa gbígbógun ti àwọn ohun tó ń fa àìfọkànbálẹ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.
“Kàn yan olórí àwọn òṣìṣẹ́ ológun tàbí adarí, se ohunkóhun-isẹ́ rẹ̀ ti parí. Àmọ́, olórí máa ń se jù báyìí lọ. O gbọ́dọ̀ ríi pé àwọn ènìyàn to bá yàn kára mọ́ iṣẹ́ wọn, wọ́n sì gbọ́dọ̀ mọ iṣẹ́ yìí.
“Tí wọn kò bá se iṣẹ́ yìí bó se yẹ, yọ wọ́n kúrò, ko sì yan àwọn ènìyàn tí wọ́n lè se iṣẹ́ yìí dáadáa.”
CableCheck tún ṣàkíyèsí pé àwọn ibi ìbáraẹnise tí Trump ń lò lórí ayélujára (Trump’s social media accounts), tí wẹbusaiti àwọn alákòóso US (White House website) àti ti àwọn ilé isẹ́ ìròyìn tí ìṣẹ́ wọn kárí ayé tí wọ́n seé gbàgbọ́ (credible international news platforms) kò sọ̀rọ̀ tó fi ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀.
BI CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
Kò sí ẹ̀rí tó sàfihàn pé Trump sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà ma yọ Tinubu kúrò nípò ààrẹ láàárín wákàtí mẹrinlelogun. Àwọn ilé isẹ́ ìròyìn tí wọ́n seé gbàgbọ́ ma ti gbé ọ̀rọ̀ síta tí Trump bá sọ ọ̀rọ̀ yìí.