Atiku Abubakar, igbá-kejì Olusegun Obasanjo, ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí tó sì tún jẹ́ olùdíje fún ipò ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ laipẹ yìí ní ibi ìpéjọ Lagos Chamber of Commerce and Industry (LCCI).
Atiku sọ ọ̀rọ̀ ní ibi ìpéjọ kan tí LCCI ṣe fún àwọn tí ó ń sòwò/ṣe ọrọ ajé tí wọn jẹ́ aladaani ti ọdún 2022.
TheCable ṣe àyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti fi ìdí òdodo múlẹ̀, èsì ìwádìí wà nìyí.
Ọ̀RỌ̀ KÍNNÍ: Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ń jẹ gbèsè láti ìgbà tí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) ti gba ìjọba ní ọdún 2015.
Àbájáde Ìwádìí: Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Láti ìgbà tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti gba ìjọba ní ọdún 2015 ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ń jẹ gbèsè.
Ikuna nínú ìṣúná owó ìjọba àpapọ̀ máa ń wáyé ní ìgbà tí ìjọba bá ná owó ju owó tí ó ń wọlé fún lọ. Economic Times ṣàlàyé pé a máa ń ṣe àkọsílẹ̀ idinku nínú owó tí ó ń wọlé fún ìjọba ni iwọnba ìpín ọgọ́rùn-ún (percentage) àpapọ̀ ọrọ̀ ajé (gross domestic product GDP).
Àyẹ̀wò Ìwé ìròyìn TheCable fihàn pé ààrẹ Mùhámádù Buhari ń ṣe àbójútó ètò ìjọba nínú gbèsè láti ìgbà tí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìjọba ni ọdún 2015. Ṣùgbọ́n, èyí ti ń dojú kọ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lábẹ́ àwọn ìjọba tí a ti ní s’ẹhin, láti ọdún 1981.
Yàtọ̀ sí ọdún 1995 ati 1996 tí ìjọba Nàìjíría ní àjẹṣẹ́kù nínú ètò ìṣúná rẹ, orílẹ̀-èdè náà ti ń jẹ gbèsè láti ọdún 1981.
Ọ̀RỌ̀ KEJÌ: “Idinku nínú ètò ìṣúná ìjọba Nàìjíríà lábẹ́ àkóso ààrẹ Buhari máa ń s’ábà kọjá ìpín mẹ́ta nínú ọgọ́rùn-ún (3%) ti òfin owo-nina-Fiscal Responsibility Act gbà láàyè.
Àbájáde Ìwádìí: Òtítọ́ ọ̀rọ̀ ni. Idinku nínú ètò ìṣúná Nàìjíríà kọjá ìpín mẹ́ta (3%) ti òfin gbà láàyè ní ọdún 2017, 2019, 2022 àti 2021, ìgbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láàrin ọdún méje.
Gẹ́gẹ́bí data láti ọ̀dọ̀ baanki àpapọ̀ Nàìjíríà (Central Bank of Nigeria) àti àwọn tí ń ṣe ètò ìṣúná ìjọba àpapọ̀ (Budget office of the federation), ti PricewaterhouseCoopers (PwC) gbé jáde, ìjọba Buhari kọjá ìpín mẹ́ta ẹ̀yáwó nínú ìpín ọgọ́rùn-ún ní ọdún 2017. Ní ọdún náà, ẹ̀yáwó orílẹ̀-èdè yìí jẹ́ 3.17%.
Ìjọba àpapọ̀ kọjá ìpín ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ẹ̀yáwó ní ọdún 2019 àti 2021, gẹ́gẹ́bí atẹjade PwC ṣe wí.
Year | Budget deficit as a percentage of GDP |
2010 | -2.o2 |
2011 | -1.84 |
2012 | -1.36 |
2013 | -1.4 |
2014 | -0.94 |
2015 | -1.65 |
2016 | -2.63 |
2017 | -3.17 |
2018 | -2.84 |
2019 | -3.41 |
2020 | -3.57 |
2021 | -3.93 |
Orísun data: Lati ọdọ ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ ti orilẹ-ede Nàìjíría, ọfiisi ètò ìṣúná ijoba àpapọ ati PwC
Òfin fún nínà owó ni ọ̀nà tí ó dára (Nigerian Fiscal Responsibility Act) ti ọdún 2007 lè gba ìjọba láàyè láti yá owó kọjá ìpín ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àpapọ̀ ọrọ̀ ajé (GDP) ní àwọn ìgbà tí nkan kò bá dára. Òfin yìí s’ètò pé ààrẹ nìkan ló lè gbé ìgbésẹ yìí.
Ikpefan Ochei, ọjọgbọn nípa ètò nina-owo ní Covenant University, sọ fún TheCable pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti kùnà láti ṣe gẹ́gẹ́bí òfin náà ti wí láti ọdún 2015, ó fi kún un wí pé ìyípadà nínú iye owó epo rọ̀bì lo faa.
“Epo rọ̀bì jẹ́ oun kan pàtàkì tí ń mú owó wọlé fún orilẹ-ede Nàìjíría. Ẹka epo rọ̀bì àti gáàsí, tí ó jẹ okùn ẹ̀mí ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè náà ti ní ipadasẹyin ni abala mọkandinlogun nínú ọgbọ̀n láti ọdún 2014, tí a bá ṣe àfiwé rẹ̀ pẹ̀lú $108.56 ní ọdún 2013 àti $111.63 ní ọdún 2012,” onímọ̀ nípa ètò owó-nina náà ló sọ bẹ́ẹ̀.
“Lábẹ́ ìjọba tiwa-n-tiwa tí ìjọba ní láti ṣ’abapade ìrètí àwọn ènìyàn, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ nínú pé kí ìjọba yá owó, ti ìjọba bá lo owó náà dáadáa.”
Ọ̀RỌ̀ KẸTA: “Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ò ní owó láti ra ọjà/oun tí wọ́n nílò. Iye owó tí wọ́n ta búrẹ́dì ti wọ́n síi níwọ̀nba ìpín ọgọ́rùn-ún ju bó ti wà ní ọdún 2020.”
Àbájáde Ìwádìí: Irọ́ ni. Ìdíyelé búrẹ́dì kan ti wọn síi pẹ̀lú ìpín mejilelaadọta (52%) fún búrẹ́dì tí a gé àti marunlelaadọta (55%) fún búrẹ́dì tí a kò gé- kìíse èlé ní ìpín ọgọ́rùn-ún bí Àtíkù ti wí.
Data láti ọwọ ẹka tí ó ń ṣe ìṣirò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (National Bureau of Statistics, NBS) ní oṣù keje, ọdún 2022 fihàn pé iye búrẹ́dì tí a gé (500g) lápapọ̀ kárí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ N486.27, ní ìgbà tí iye búrẹ́dì tí a kò gé jẹ́ N447.16.
Ẹ̀wẹ̀, ní oṣù keje, ọdún 2020, iye búrẹ́dì tí a gé (500g) lápapọ̀ kárí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ N318.5, ní ìgbà tí iye búrẹ́dì tí a kò gé (500g) lápapọ̀ jẹ́ N287.7.
Ìyàtọ̀ nínú iye búrẹ́dì tí a gé (500g) lápapọ̀ láàárín oṣù keje, ọdún 2020 àti osu keje ọdún 2022 jẹ́ N167.7, èyí túmọ̀ sí pé àfikún 52.6 percent ló wáyé; ìyàtọ̀ nínú iye búrẹ́dì tí a kò gé láàárín ọdún méjèèjì jẹ́ N159.46, èyí túmọ̀ sí àfikún ìpín marunlelaadọta àti díẹ̀ (55.4 percent).
July 2020 | July 2022 | Average increase in Naira. | Percentage increase | |
Average Cost of Slice Bread (500g) | N318.5 | N486.27 | N167.7 | 52.6 |
Average Cost of Unsliced Bread | N287.7 | N447.16 | N159.46 | 55.4 |
Ọ̀RỌ̀ KẸRIN: “Àwọn àgbẹ̀ ń san iye ìpín ọgọ́rùn-ún lọ́nà igba fún ajílẹ̀ àpò kan, èyí tí ó ju iye tí wọn ń san ní ọdún 2020.
Àbájáde Ìwádìí: Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Iye owó tí wọ́n ta ajílẹ̀ ti lé si pẹ̀lú ìpín ọdunrun (300%).
Ẹ̀yà ajílẹ̀ tí àwọn àgbẹ̀ Nàìjíríà máa ń s’ábà lo ni NPK àti urea.
Ní ọdún 2020, ìjọba àpapọ̀ dín iye àádọta kílò ajílẹ̀ NPK 20.10.10 láti N5,500 kù sí N5,000 l’abẹ àsíá presidential fertiliser initiative (PFI).
Igbesẹ yìí jẹ ọ̀kan nínú àwọn ǹkan tí ìjọba ń ṣe láti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn àgbẹ̀ àti láti mú idinku bá ìpalára ààrùn Covid19 lórí iṣẹ́ àgbẹ̀ àti àwọn tí ó ń bá wọn ra nkan.
Data láti ọ̀dọ̀ Africa Fertilizer àti International Fertilizer Development Center (IFDC) tí wọ́n gbé jáde ní oṣù kẹta ọdún 2022 s’àyẹ̀wò iye tí wọn ta ajílẹ̀ NPK 20:10:10; NPK 15:15:15 àti urea ni Ìpínlẹ̀ mẹ́fà wọ̀nyí: Niger, Kwara, Edo, Anambra, Kano ati Kaduna.
Wọ́n ta ajílẹ̀ urea ní N16,500 ni oṣù kẹta, ọdún 2022, ni ìgbà tí iye ajílẹ̀ NPK 20:10:10 jẹ́ N15,400, wọn sì ta ajílẹ̀ NPK 15:15:15 ní N16,500.
Tí a bá ṣe àfiwé iye tí wọn ta ajílẹ̀ ní 2020 (N5,000) àti iye ajílẹ̀ NPK ní oṣù kẹta, ọdún 2022, a ríi wí pé iye náà lé pẹlu ìpín ní ọna ìgbà àti ọgbọn (230 percent).
Lẹ́yìn oṣù márùn-ún, Gideon Nagedu, ẹni tí ó jẹ́ akọwe ẹgbẹ́ tí ó ń ṣe ajilẹ àti àwọn tí ó ń pèsè rẹ-Fertiliser Producers and Suppliers Association of Nigeria (FEPSAN) fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé iye owó tí wọn ta ajílẹ̀ ti lé sí pẹlu ìpín ọdunrun (300 percent) káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
”Ìgbà àkọ́kọ́ tí yóò lọ sókè síi pẹ̀lú ìpín ní ọna ọdunrun ni èyí. Irú nkan báyìí kò ṣẹlẹ̀ rí. Kìíse orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nìkan ni èyí ti wáyé, ìṣòro tó wà níbẹ̀ nìyí,” Nagedu ló sọ báyìí.
Ìjọba Nàìjíríà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ara ǹkan tó ń s’okùnfà kí iye ajílẹ̀ lé owó síi ni ogun tó bẹ́ silẹ láàrín orílẹ̀-èdè Russia àti Ukraine.
Ọ̀RỌ̀ KARUN: Onka nípa àwọn ọdọ tí kò rí iṣẹ́ ṣe lé sí ní ìlọ́po mílíọ̀nù mẹsan láti mílíọ̀nù mẹ́rin ní ọdún 2015 sí mílíọ̀nù mẹ́tàlá ní ọdún 2020.
Àbájáde Ìwádìí: Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. A ríi wí pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Àtíkù sọ wí pé iye àwọn ọ̀dọ́ tí kò rí iṣẹ́ ṣe ni Nàìjíríà ti pọ̀ sí pẹ̀lú ìlọ́po mílíọ̀nù mẹsan láàrín ọdún 2015 sí 2020.
TheCable s’àyẹ̀wò data ti àjọ NBS gbé kalẹ lórí airiṣẹṣe ni ọdún 2015 àti 2020.
A ṣe aropọ data fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ọjọ́ orí wọn wà ní ọdún marundinlogun sí mẹ́rìnlélógún (15-24 years) àti ọjọ́ orí marundinlọgbọn sí mẹrinlelọgbọn (25-34), a ríi dájú wí pé ní ọdún 2015, data fún airiṣẹṣe àwọn ọdọ jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́ta lé ní ẹgbẹ̀rún ní ọna ẹẹdẹgbẹrin ó dín ni àádọ́ta ẹgbẹ̀rún (3.65m), miliọnu mẹ́rin (4m), milliọnu márùn-ún dín ní ẹgbẹ̀rún ní ọna ogójì (4.96m) àti miliọnu marun ó lè ní ẹgbẹ̀rún ní ọna Ọọdunrun (5.30m) ni ida mẹ́rin ọdún náà.
Àjọ NBS gbé data jáde fún iye òṣìṣẹ́ tó wà ní Nàìjíríà ní ìdáméjì ati idamẹrin ọdún 2020. Ni ìdáméjì ọdún náà (Q2), iye ènìyàn tí kò rí iṣẹ́ ṣe jẹ́ miliọnu mẹ́rìnlá dín ní igba ẹgbẹ̀rún (13.98m), ni idamẹrin ọdún náà, iye ènìyàn miliọnu méjìlá àti ẹẹdẹgbẹrìn ẹgbẹ̀rún ó lè díẹ̀ ni kò ní iṣẹ́ lọ́wọ́.
Ọ̀RỌ̀ KẸFÀ: “Láàrín ọdún márùn-ún (2015 sí 2020), iye ènìyàn tó ń ṣiṣẹ́ dínkù pẹ̀lú ìpín ẹẹrinleniaadọta (54%) láti miliọnu mejidinlaadọrin (68m) sí miliọnu mọkanlelọgbọn (31m).
Àbájáde Ìwádìí: Irọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Kò sí àkókò kankan ní ọdún 2015 tí iye ènìyàn tó ń ṣiṣẹ́ lójú mejeeji jẹ́ miliọnu mejidinlaadọrin (68m), tí a bá lo data láti ọdọ NBS.
Data NBS fihàn pé miliọnu mẹtalelogun àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rùn-ún (23.1 million) ènìyàn nínú iye òṣìṣẹ́ àádọ́rin miliọnu ó dín miliọnu kan àti ẹgbẹ̀rún ni ọna ẹgbẹ̀ta (69.6 million) ni kò rí iṣẹ́ ṣe ni idamẹrin ọdún 2020.
Ní idà àkọ́kọ́ ọdún 2015, data NBS fihàn pé iye ènìyàn tó ń ṣiṣẹ́ lójú méjèèjì jẹ miliọnu marunlelaadọta àti ẹgbẹ̀rún ní ọna ẹẹdẹgbẹrìn ó dín ẹgbẹ̀rún mẹwa (55.69 million); ni ìdáméjì ọdún náà, data náà jẹ́ miliọnu mẹrinlelaadọta àti ẹgbẹ̀rún ni ọna àádọ́rin lé ní ọọdunrun (54.37 million); ní idamẹta ọdún, data náà jẹ́ miliọnu marunlelaadọta ó lé ní ìgbà ẹgbẹ̀rún ó lé ní mẹwa (55.21 million), ní idamẹrin ọdún, data náà jẹ miliọnu mẹrinlelaadọta ó lé ní ẹgbẹ̀rún ní ọna ẹẹdẹgbẹta (54.50 million).
Àjọ NBS gbé data jáde fún iye àwọn òṣìṣẹ́ ní ìdáméjì ati idamẹrin ọdún 2020. Iye ènìyàn tó ń ṣiṣẹ́ lójú méjèèjì ní ìdáméjì ọdún náà jẹ miliọnu marundinniogoji ó lé ní ẹgbẹ̀rún ní ọna ẹẹdẹgbẹta (35.5 million), ní idamẹrin ọdún náà, iye ènìyàn tó ń ṣiṣẹ́ jẹ́ ọgbọn miliọnu ó lé ní ẹgbẹ̀rún ní ọna ẹẹdẹgbẹta lé ní àádọ́rin (30.57 million).
Ní ìgbà tí a ṣe àfiwé iye ènìyàn tó ní iṣẹ́ lọ́wọ́ ní idamẹrin ọdún 2015 àti 2020, a ríi wí pé ìyàtọ̀ ìpín ẹ̀taléníogójì ó lé díẹ̀ (43.90 percent). A ṣe àfiwé náà fún ìdáméjì ọdún 2015 àti 2020, a rí ìyàtọ̀ ìpín mẹ̀rinléníọgbọ̀n ó lé ní díẹ̀ (34.55 percent).
Ọ̀RỌ̀ KEJE: Ètò iná mọnamọna wà lábẹ́ àwọn nkan tí òfin fún ìjọba àpapọ̀ nìkan láti darí ẹ (exclusive legislative list).
Àbájáde Ìwádìí: Èyí kìíse òtítọ́. Iná mọnamọna wà lábẹ́ àwọn nkan tí ìjọba àpapọ̀ àti ìjọba Ìpínlẹ̀ lé sofin nípa ẹ tàbí darí ẹ (concurrent legislative list).
Nínú àlàyé rẹ lórí bí yóò ṣe mú ìdàgbàsókè bá ẹ̀ka tí ó ṣ’eto iná mọnamọna, Àtíkù wí pé, ”Ní àsìkò díẹ̀, màá ṣe ètò òfin ti yóò yọ ètò ina mọnamọna kúrò nínú àwọn oun tí òfin fún ìjọba àpapọ̀ nìkan láyè láti darí rẹ, èyí yóò gba àwọn ìjọba Ìpínlẹ̀ láàyè láti pèsè àti pín ina mọnamọna fún àwọn ènìyàn wọn.”
Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń lo ètò ìjọba àpapọ̀, òfin orílẹ̀-èdè náà fi àyè sílẹ̀ fún pínpín agbára/ìṣètò/ìṣàkóso láàrin ìjọba gbogbogbò, ijoba ìpínlẹ̀ àti ìjọba agbègbè. Nítorí náà, a ní àwọn nkan tí òfin fi àyè gba ìjọba àpapọ̀ nìkan láti ṣ’ètò tàbí ṣàkóso lórí/nípa wọn (exclusive legislative list), àwọn nkan tí òfin fún ìjọba àpapọ̀ àti àwọn ìjọba Ìpínlẹ̀ nìkan láti ṣ’ètò/s’àkóso lórí/nípa wọn (concurrent legislative list), àti àwọn oun tí òfin fún ìjọba agbègbè láyè láti s’ètò/ṣàkóso lórí/nípa wọn (residual legislative list).
Àtòjọ isofin iyasọtọ je ti ijoba àpapọ̀. Àtòjọ isofin ni ṣiṣentẹle fún ìjọba àpapọ̀ àti ìjọba ipinle láàyè lati se òfin, lórí majẹmu wipe ti idojukọ bá ṣẹlẹ, tí a bá rí oun tí kò dára tó tí ó gba kí a yanjú rẹ̀ ní wàràǹṣesà, ìjọba àpapọ̀ ni òfin fún láyè láti ṣe oun tí ó yẹ.
Ilé igbimọ aṣofin Ìpínlẹ ní agbára láti ṣe òfin lórí àwọn oun tí ó wà lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba àgbègbè tí kò sí nínú àwọn oun tí ó wà lábẹ́ ìṣàkóso ijoba àpapọ̀ tàbí ìjọba Ìpínlẹ̀.
Ètò iná mọnamọna kò sí lára àwọn oun mejidinlaadọrin nínú àwọn oun tí ó jẹ wí pé ìjọba àpapọ̀ nìkan ni ó lè ṣe ìṣàkóso wọn nínú ìwé òfin tí ọdún 1999.
TheCable fi ọ̀rọ̀ wá amofin Olusola Akin Yemi lẹ́nu wò nípa ọrọ yi.
”Apá kejì ti ìwé òfin ti ọdún 1999, lábẹ́ ìpínrọ kẹtàlá àti kẹrìnlá, fi lélẹ̀ pé ìjọba ìpínlẹ̀ le s’agbekalẹ àti pin iná fún àwọn agbègbè tí kò sí lábẹ́ bí a ti ṣe ń pín iná ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (national grid system),” amofin náà ló sọ báyìí.
Akinyemi fi kún-un wí pé Àtíkù lè máa gbìyànjú láti sàlàyé pé tí wọn bá yan òun sì ipo ààrẹ, ìjọba òun yóò fún ìjọba ìpínlẹ̀ ní agbára láti pèsè ati pín iná mọnamọna sí àgbègbè tó wà lábẹ́ ètò bí a ṣe ń pín iná ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (national grid system.